Who cast that first fateful tomato that started the La Tomatina revolution? The reality is no one knows. Maybe it was an anti-Franco rebellion, or a carnival that got out of hand. According to the most popular version of the story, during the 1945 festival of Los Gigantes (a giant paper mâché puppet parade), locals were looking to stage a brawl to get some attention. They happened upon a vegetable cart nearby and started hurling ripe tomatoes. Innocent onlookers got involved until the scene escalated into a massive melee of flying fruit. The instigators had to repay the tomato vendors, but that didn't stop the recurrence of more tomato fights—and the birth of a new tradition.
Fearful of an unruly escalation, authorities enacted, relaxed, and then reinstated a series of bans in the 1950s. In 1951, locals who defied the law were imprisoned until public outcry called for their release. The most famous effrontery to the tomato bans happened in 1957 when proponents held a mock tomato funeral complete with a coffin and procession. After 1957, the local government decided to roll with the punches, set a few rules in place, and embraced the wacky tradition.
Though the tomatoes take center stage, a week of festivities lead up to the final showdown. It's a celebration of Buñol's patron saints, the Virgin Mary and St. Louis Bertrand, with street parades, music, and fireworks in joyous Spanish fashion. To build up your strength for the impending brawl, an epic paella is served on the eve of the battle, showcasing an iconic Valencian dish of rice, seafood, saffron, and olive oil.
Today, this unfettered festival has some measure of order. Organizers have gone so far as to cultivate a special variety of unpalatable tomatoes just for the annual event. Festivities kick off around 10 a.m. when participants race to grab a ham fixed atop a greasy pole. Onlookers hose the scramblers with water while singing and dancing in the streets. When the church bell strikes noon, trucks packed with tomatoes roll into town, while chants of "To-ma-te, to-ma-te!" reach a crescendo.
Then, with the firing of a water cannon, the main event begins. That's the green light for crushing and launching tomatoes in all-out attacks against fellow participants. Long distance tomato lobbers, point-blank assassins, and medium range hook shots. Whatever your technique, by the time it's over, you will look (and feel) quite different. Nearly an hour later, tomato-soaked bombers are left to play in a sea of squishy street salsa with little left resembling a tomato to be found. A second cannon shot signals the end of the battle. | Tani ó ju tòmátì àkọ́kọ́ náà tí ó mú kí rògbòdìyàn La Tomatina bẹ̀rẹ̀? Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí ẹnití ó mọ̀. Bóyá ìṣọ̀tẹ̀ ìṣòdì Faranse ni, tàbí àjọ̀dún kan tí kò ṣe é ṣàkóso mọ́. Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí ó wọ́pọ̀ jùlọ nípa ìtàn náà, lásìkò ayẹyẹ Los Gigantes ní ọdún 1945 (ìwọ́de àwọn ère nlá tí a fi amọ̀ oní-pépà ṣe), àwọn ara ìlú nwá ọ̀nà láti dá ìjà sílẹ̀ kí àwọn ènìyàn lè ṣàkíyèsi wọn. Wọ́n rí ọmọlanke kan tí ó kó oríṣiríṣi ewébẹ̀ àti èso nítòsí wọn lójijì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síí ní ju àwọn tòmátì tó ti pọ́n nínú rẹ̀ nù. Àwọn òwòran tí kò mọ ohun tí nlọ náà darapọ̀ mọ́ wọn, títí tí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà fi di ibi ìdàrúdàpọ̀ àwọn èso tí nfò kiri. Àwọn ọ̀dádá náà ní láti san àsanpadà fún àwọn tó ni tòmátì náà, ṣùgbọ́n èyí kò dá wíwáyé àwọn ìjà tòmátì náà nígbà mìíràn dúró —àti ìbẹ̀rẹ̀ àṣà titun. Nítorí ìbẹ̀rù pé kí ìjà náà má di ti ìgboro, àwọn aláṣẹ ìlú gbé àwọn oríṣiríṣi òfin tó de àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀ jáde ni àwọn ọdún 1950, wọ́n dẹ àwọn òfin náà nílẹ̀ díẹ̀, wọ́n sì tún mú wọn le síi. Ní ọdún 1951, àwọn ara ìlú tí ó tàpá sí òfin náà ni a tì mọ́lé títí di ìgbà tí ariwo àwọn ara ìlú bèèrè fún ìtúsílẹ̀ wọn. Àfojúdi tí ó lókìkí jùlọ sí awọn òfin tó de ni mọ́lẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ tòmátì náà ni ó wáyé ọdún 1957 nígbàtí àwọn kan ṣe ìsìnkú yẹ̀yẹ́ fún tòmátì pẹ̀lú pósí àti àpéjọ àwọn ènìyàn. Lẹ́yìn ọdún 1957, ìjọba ìbílẹ̀ pinnu láti da ara wọn pọ̀ mọ́ ohun tí n ṣẹlẹ̀, gbé àwọn òfin melo kan jáde, kí wọ́n sì tẹ́wọ́gba àṣà apanilẹ́ẹ̀rín náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tòmátì náà ni ó wọ́pọ̀ jù, ayẹyẹ lọ fún odindin ọ̀sẹ̀ kan títí di ìgbà ìjàkadì ìkẹyìn. Ó jẹ́ àkókò ayẹyẹ àwọn baba ìsàlẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ Buñol, Maria Wúndíá àti ti St. Louis Bertrand, pẹ̀lú ìwọ́de ojú pópó, orin àti àwọn ohun ìṣeré tí n tanná gẹ́gẹ́ bí àṣà ìdùnnú àwọn ara Sípéènì. Láti fi agbára kún ara ẹni ní ìmúrasílẹ̀ ìjàkadì tí mbọ̀ lọ́nà, a má a n se ìrẹsì pàtàkì kan pẹ̀lú adìẹ àti àwọn oúnjẹ tí à nrí láti inú omi bíi ẹja, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ní alẹ́ ọjọ́ tí ó ṣáájú ìjàkadì náà, èyí tí n ṣàfihàn oúnjẹ akọni àwọn ara Valencia pẹ̀lú ìrẹsì, àwọn oríṣiríṣi oúnjẹ tí a n rí láti inú omi, èròjà oúnjẹ tí a n pé ní saffron,àti òróró ólífì. Lónìí, ayẹyẹ aláìní ìhámọ́ yìí ti ní ìlànà ètò díẹ̀ síi. Àwọn olùṣètò ti tẹ̀síwájú dé ibi pé wọn a má a gbin oríṣi tòmátì tí kò dùn rárá kan fún ayẹyẹ ọlọ́dọọdún náà. Ayẹyẹ a má a bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́ẹ̀wá òwúrọ̀, nígbàtí àwọn olùkópa a má a súré lọ láti lọ gbá ẹran ẹlẹ́dẹ̀ tí a so mọ́ òkè òpó elépo lára kan mú. Àwọn òwòran a má a lo okún oníhò tí a fi nfa omi láti fi fún omi sí àwọn ajìfà náà lára bí wọ́n ti nkọrin, tí wọ́n sì njó ní ojú òpópó. Nígbàtí aago ilé ìjọ́sìn bá lu mejila ọ̀sán, àwọn ọkọ̀ akẹ́rù tí ó kún fún tòmátì yóò yí wọlé sínú ìlú, nígbàtí ariwo "To-ma-te, to-ma-te!" yóò wá gba gbogbo òde kan. Nígbà náà, nípasẹ̀ omi fífọ́n kiri láti inú ìgò, ìṣẹ̀lẹ̀ náà gan-an-gan yóò wá bẹ̀rẹ̀. Ààmì ìtẹ̀síwájú ni èyí fún fífọ́ sí wẹ́wẹ́ àti jíju tòmátì káàkiri nínú ìdojú ìjà kọ àwọn ẹlẹgbẹ́ olùkópa. Àwọn ènìyàn tí ó mọ tòmátì jù láti ọ̀nà jíjìn, àwọn ògbójú apànìyàn, àti àwọn tó mọ̀ ọ́ jù láti ìtòsí yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ́ lókò. Oríṣi ọ̀nà yòówù tí ìwọ bá mọ̀ ọ́ lò, nígbàtí ohun gbogbo yóò bá fi parí, ìwọ kì yóò jẹ́ ara rẹ mọ́. Bíi wákàtí kan lẹ́yìn náà, a ó fi àwọn tó mọ tòmátì jù bíi àdó olóró sẹ́yìn láti má a gbé ẹsẹ̀ ijó lọ́kọ̀ọ̀kan láàárín ọbẹ̀ tí kò sí ohun tí ó fi jọ ọbẹ̀ tòmátì mọ́. Omi fífọ́n káàkiri ẹlẹ́ẹ̀kejì ni ó jẹ́ ààmì òpin ìjàkadì náà. |